Efe 5:9-13

Efe 5:9-13 YBCV

(Nitori eso Ẹmí wà niti iṣore gbogbo, ati ododo, ati otitọ;) Ẹ si mã wadi ohun ti iṣe itẹwọgbà fun Oluwa. Ẹ má si ba aileso iṣẹ òkunkun kẹgbẹ pọ̀, ṣugbọn ẹ kuku mã ba wọn wi. Nitori itiju tilẹ ni lati mã sọ̀rọ nkan wọnni ti nwọn nṣe nikọ̀kọ. Ṣugbọn ohun gbogbo ti a mba wi ni imọlẹ ifi han: nitori ohunkohun ti o ba fi nkan hàn, imọlẹ ni.