Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi ọ̀rọ asan tàn nyin jẹ: nitori nipasẹ nkan wọnyi ibinu Ọlọrun mbọ̀ wá sori awọn ọmọ alaigbọran. Nitorina ẹ máṣe jẹ alajọpin pẹlu wọn. Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ: (Nitori eso Ẹmí wà niti iṣore gbogbo, ati ododo, ati otitọ;) Ẹ si mã wadi ohun ti iṣe itẹwọgbà fun Oluwa. Ẹ má si ba aileso iṣẹ òkunkun kẹgbẹ pọ̀, ṣugbọn ẹ kuku mã ba wọn wi. Nitori itiju tilẹ ni lati mã sọ̀rọ nkan wọnni ti nwọn nṣe nikọ̀kọ. Ṣugbọn ohun gbogbo ti a mba wi ni imọlẹ ifi han: nitori ohunkohun ti o ba fi nkan hàn, imọlẹ ni. Nitorina li o ṣe wipe, Jí, iwọ ẹniti o sùn, si jinde kuro ninu okú, Kristi yio si fun ọ ni imọlẹ. Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; Ẹ mã ra ìgba pada, nitori buburu li awọn ọjọ. Nitorina ẹ máṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ mã moye ohun ti ifẹ Oluwa jasi.
Kà Efe 5
Feti si Efe 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 5:6-17
21 Days
In the 21 Days to Overflow YouVersion plan, Jeremiah Hosford will take readers on a 3-week journey of emptying themselves of themselves, being filled with the Holy Spirit, and living out an overflowing, Spirit-filled life. It’s time to stop living normally and start living an overflowing life!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò