Efe 5:25-29

Efe 5:25-29 YBCV

Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rẹ̀ fun u; Ki on ki o le sọ ọ di mimọ́ lẹhin ti a ti fi ọ̀rọ wẹ ẹ mọ́ ninu agbada omi, Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rẹ̀ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ́ ati alaini àbuku. Bẹ̃li o tọ́ ki awọn ọkunrin ki o mã fẹràn awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikarawọn. Ẹniti o ba fẹran aya rẹ̀, o fẹran on tikararẹ̀. Nitori kò si ẹnikan ti o ti korira ara rẹ̀; bikoṣepe ki o mã bọ́ ọ ki o si mã ṣikẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi si ti nṣe si ìjọ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Efe 5:25-29