Efe 5:15-21

Efe 5:15-21 YBCV

Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; Ẹ mã ra ìgba pada, nitori buburu li awọn ọjọ. Nitorina ẹ máṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ mã moye ohun ti ifẹ Oluwa jasi. Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí; Ẹ si mã bá ara nyin sọ̀rọ ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã kọrin, ki ẹ si mã kọrin didun li ọkàn nyin si Oluwa; Ẹ mã dupẹ nigbagbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa; Ẹ mã tẹriba fun ara nyin ni ìbẹru Ọlọrun.