Efe 4:4-8

Efe 4:4-8 YBCV

Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin; Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan, Ọlọrun kan ati Baba gbogbo, ẹniti o wà lori gbogbo ati nipa gbogbo ati ninu nyin gbogbo. Ṣugbọn olukuluku wa li a fi ore-ọfẹ fun gẹgẹ bi oṣuwọn ẹ̀bun Kristi. Nitorina o wipe, Nigbati o gòke lọ si ibi giga, o di igbekun ni igbekun, o si fi ẹ̀bun fun enia.