Efe 4:28-32

Efe 4:28-32 YBCV

Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini. Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́. Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande. Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn: Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Efe 4:28-32

Efe 4:28-32 - Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini.
Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́.
Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.
Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn:
Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.Efe 4:28-32 - Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini.
Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́.
Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.
Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn:
Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.