Efe 3:7-13

Efe 3:7-13 YBCV

Iranṣẹ eyiti a fi mi ṣe gẹgẹ bi ẹ̀bun ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀. Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ́, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamáridi ọrọ̀ Kristi fun awọn Keferi; Ati lati mu ki gbogbo enia ri kini iṣẹ-iriju ohun ijinlẹ na jasi, eyiti a ti fi pamọ́ lati aiyebaiye ninu Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi: Ki a ba le fi ọ̀pọlọpọ onirũru ọgbọ́n Ọlọrun hàn nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ, Gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa: Ninu ẹniti awa ni igboiya, ati ọ̀na pẹlu igbẹkẹle nipa igbagbọ́ wa ninu rẹ̀. Nitorina mo bẹ̀ nyin ki ãrẹ̀ ki o máṣe mu nyin ni gbogbo wahalà mi nitori nyin, ti iṣe ogo nyin.