Efe 3:14-20

Efe 3:14-20 YBCV

Nitori idi eyi ni mo ṣe nfi ẽkun mi kunlẹ fun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Orukọ ẹniti a fi npè gbogbo idile ti mbẹ li ọrun ati li aiye, Ki on ki o le fifun nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ ogo rẹ̀, ki a le fi agbara rẹ̀ mú nyin li okun nipa Ẹmí rẹ̀ niti ẹni inu; Ki Kristi ki o le mã gbé inu ọkàn nyin nipa igbagbọ; pe bi ẹ ti nfi gbongbo mulẹ, ti ẹ si nfi ẹsẹ mulẹ ninu ifẹ, Ki ẹnyin ki o le li agbara lati mọ̀ pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́, kini ìbú, ati gigùn, ati jijìn, ati giga na jẹ, Ati lati mọ ifẹ Kristi ti o ta ìmọ yọ, ki a le fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọrun kun nyin. Njẹ ẹniti o le ṣe lọpọlọpọ jù gbogbo eyiti a mbère tabi ti a nrò lọ, gẹgẹ bi agbara ti nṣiṣẹ ninu wa