Efe 3:1-6

Efe 3:1-6 YBCV

NITORI eyina, emi Paulu, ondè Jesu Kristi nitori ẹnyin Keferi, Bi ẹnyin ba ti gbọ ti iṣẹ iriju ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun mi fun nyin: Bi o ti ṣepe nipa ifihan li o ti fi ohun ijinlẹ nì hàn fun mi, (gẹgẹ bi mo ti kọ ṣaju li ọrọ diẹ, Nigbati ẹnyin ba kà a, nipa eyi ti ẹnyin ó fi le mọ oye mi ninu ijinlẹ Kristi,) Eyiti a kò ti fihàn awọn ọmọ enia rí ni irandiran miran, bi a ti fi wọn hàn nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ́ ati awọn woli nipa Ẹmí; Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere