Efe 2:3-7

Efe 2:3-7 YBCV

Ninu awọn ẹniti gbogbo wa pẹlu ti wà rí ninu ifẹkufẹ ara wa, a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ; ati nipa ẹda awa si ti jẹ ọmọ ibinu, gẹgẹ bi awọn iyoku pẹlu. Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa, Nigbati awa tilẹ ti kú nitori irekọja wa, o sọ wa di ãye pẹlu Kristi (ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin là). O si ti ji wa dide pẹlu rẹ̀, o si ti mu wa wa joko pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun ninu Kristi Jesu: Pe ni gbogbo ìgba ti mbọ ki o ba le fi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀ ti o pọ rekọja han ninu iṣeun rẹ̀ si wa ninu Kristi Jesu.