Efe 2:19-21

Efe 2:19-21 YBCV

Njẹ nitorina ẹnyin kì iṣe alejò ati atipo mọ́, ṣugbọn àjumọ jẹ ọlọ̀tọ pẹlu awọn enia mimọ́, ati awọn ará ile Ọlọrun; A si ngbé nyin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn woli, Jesu Kristi tikararẹ̀ jẹ pàtaki okuta igun ile; Ninu ẹniti gbogbo ile na, ti a nkọ ṣọkan pọ, ndagbà soke ni tẹmpili mimọ́ ninu Oluwa