Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa. Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, ẹniti o ti fi gbogbo ibukún ẹmí ninu awọn ọrun bukún wa ninu Kristi: Ani gẹgẹ bi o ti yàn wa ninu rẹ̀ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ki awa ki o le jẹ mimọ́ ati alailabùku niwaju rẹ̀ ninu ifẹ: Ẹniti o ti yàn wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara rẹ̀, gẹgẹ bi ìdunnú ifẹ rẹ̀: Fun iyin ogo ore-ọfẹ rẹ̀, eyiti o dà lù wa ninu Ayanfẹ nì: Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀; Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọ́n ati oye, Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀, Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀
Kà Efe 1
Feti si Efe 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 1:2-10
12 Days
Everyone wants to know what true love is. But few people look at what the Bible says about love. Love is one of the central themes of Scripture and the most essential virtue of the Christian life. This plan from Thistlebend Ministries explores the biblical meaning of love and how to love God better and love others.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò