Nitori eyi, emi pẹlu, nigbati mo ti gburó igbagbọ ti mbẹ larin nyin ninu Jesu Oluwa, ati ifẹ nyin si gbogbo awọn enia mimọ́, Emi kò si simi lati mã dupẹ nitori nyin, ati lati mã darukọ nyin ninu adura mi; Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀: Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ, Ati agbara rẹ̀ ti o tobi julọ si awa ti o gbagbọ́, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, Eyiti o ti ṣiṣẹ ninu Kristi, nigbati o ti jí dide kuro ninu okú, ti o si fi i joko li ọwọ́ ọtún ninu awọn ọrun, Ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ̀ pẹlu.
Kà Efe 1
Feti si Efe 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 1:15-21
12 Days
Everyone wants to know what true love is. But few people look at what the Bible says about love. Love is one of the central themes of Scripture and the most essential virtue of the Christian life. This plan from Thistlebend Ministries explores the biblical meaning of love and how to love God better and love others.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò