Efe 1:1-10

Efe 1:1-10 YBCV

PAULU, Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, si awọn enia mimọ́ ti o wà ni Efesu, ati si awọn onigbagbọ ninu Kristi Jesu: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa. Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, ẹniti o ti fi gbogbo ibukún ẹmí ninu awọn ọrun bukún wa ninu Kristi: Ani gẹgẹ bi o ti yàn wa ninu rẹ̀ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ki awa ki o le jẹ mimọ́ ati alailabùku niwaju rẹ̀ ninu ifẹ: Ẹniti o ti yàn wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara rẹ̀, gẹgẹ bi ìdunnú ifẹ rẹ̀: Fun iyin ogo ore-ọfẹ rẹ̀, eyiti o dà lù wa ninu Ayanfẹ nì: Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀; Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọ́n ati oye, Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀, Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀