Oni 9:9-10

Oni 9:9-10 YBCV

Ma fi ayọ̀ ba aya rẹ gbe ti iwọ fẹ ni gbogbo ọjọ aiye asan rẹ, ti o fi fun ọ labẹ õrùn ni gbogbo ọjọ asan rẹ: nitori eyini ni ipin tirẹ li aiye yi, ati ninu lãla ti iwọ ṣe labẹ õrùn. Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè.