Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn. Nitoripe enia pẹlu kò mọ̀ ìgba tirẹ̀; bi ẹja ti a mu ninu àwọn buburu, ati bi ẹiyẹ ti a mu ninu okùn; bẹ̃li a ndẹ awọn ọmọ enia ni ìgba buburu, nigbati o ṣubu lù wọn lojiji. Ọgbọ́n yi ni mo ri pẹlu labẹ õrùn, o si dabi ẹnipe o tobi fun mi. Ilu kekere kan wà, ati enia diẹ ninu rẹ̀; ọba nla kan si ṣigun tọ̀ ọ lọ, o si dótì i, o si mọ ile-iṣọ ti o tobi tì i. A si ri ọkunrin talaka ọlọgbọ́n ninu rẹ̀, on si fi ọgbọ́n rẹ̀ gbà ilu na silẹ; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o ranti ọkunrin talaka na. Nigbana ni mo wipe, Ọgbọ́n san jù agbara lọ; ṣugbọn a kẹgan ọgbọ́n ọkunrin talaka na, ohùn rẹ̀ kò si to òke. A ngbọ́ ọ̀rọ ọlọgbọ́n enia ni pẹlẹ jù igbe ẹniti njẹ olori ninu awọn aṣiwère. Ọgbọ́n san jù ohun-elo ogun: ṣugbọn ẹ̀lẹṣẹ kan o ba ohun didara pupọ jẹ.
Kà Oni 9
Feti si Oni 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Oni 9:11-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò