Oni 7:15-18

Oni 7:15-18 YBCV

Ohun gbogbo ni mo ri li ọjọ asan mi: olõtọ enia wà ti o ṣegbé ninu ododo rẹ̀, ati enia buburu wà ti ọjọ rẹ̀ pẹ ninu ìwa buburu rẹ̀. Iwọ máṣe ododo aṣeleke; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fi ara rẹ ṣe ọlọgbọ́n aṣeleke: nitori kini iwọ o ṣe run ara rẹ? Iwọ máṣe buburu aṣeleke, bẹ̃ni ki iwọ ki o má ṣiwère; nitori kini iwọ o ṣe kú ki ọjọ rẹ ki o to pe? O dara ki iwọ ki o dì eyi mu; pẹlupẹlu iwọ máṣe yọ ọwọ rẹ kuro ninu eyi: nitori ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ni yio yọ kuro ninu rẹ̀ gbogbo.