Nitoripe nipa ọ̀pọlọpọ iṣẹ ni alá ti iwá; bẹ̃ni nipa ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ li ã mọ̀ ohùn aṣiwère. Nigbati iwọ ba jẹ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a: nitori kò ni inu-didun si aṣiwère: san eyi ti iwọ jẹjẹ́. O san ki iwọ ki o má jẹ ẹjẹ́, jù ki iwọ ki o jẹ ẹjẹ́, ki o má san a. Máṣe jẹ ki ẹnu rẹ ki o mu ara rẹ ṣẹ̀: ki iwọ ki o má si ṣe wi niwaju iranṣẹ Ọlọrun pe, èṣi li o ṣe: nitori kili Ọlọrun yio ṣe binu si ohùn rẹ, a si ba iṣẹ ọwọ rẹ jẹ? Nitoripe bi ninu ọ̀pọlọpọ alá ni asan wà, bẹ̃ni ninu ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ pẹlu: ṣugbọn iwọ bẹ̀ru Ọlọrun.
Kà Oni 5
Feti si Oni 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Oni 5:3-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò