Bi iwọ kò ti mọ ipa-ọ̀na afẹfẹ, tabi bi egungun ti idàgba ninu aboyun: ani bẹ̃ni iwọ kò le mọ̀ iṣẹ Ọlọrun ti nṣe ohun gbogbo. Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati li aṣãlẹ máṣe da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ̀ eyi ti yio ṣe rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna. Nitõtọ imọlẹ dùn ati ohun didara ni fun oju lati wò õrùn. Ṣugbọn bi enia wà li ọ̀pọlọpọ ọdun, ti o si nyọ̀ ninu gbogbo wọn, sibẹ, jẹ ki o ranti ọjọ òkunkun pe nwọn o pọ̀. Ohun gbogbo ti mbọ̀, asan ni. Mã yọ̀, iwọ ọdọmọde ninu ewe rẹ; ki o si jẹ ki ọkàn rẹ ki o mu ọ laraya li ọjọ ewe rẹ, ki o si ma rìn nipa ọ̀na ọkàn rẹ ati nipa irí oju rẹ; ṣugbọn iwọ mọ̀ eyi pe, nitori nkan wọnyi Ọlọrun yio mu ọ wá si idajọ. Nitorina ṣi ibinujẹ kuro li aiya rẹ, ki o si mu ibi kuro li ara rẹ: nitoripe asan ni igba-ewe ati ọmọde.
Kà Oni 11
Feti si Oni 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Oni 11:5-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò