Deu 7:3-4

Deu 7:3-4 YBCV

Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá wọn dá ana; ọmọbinrin rẹ ni iwọ kò gbọdọ fi fun ọmọkunrin rẹ̀, ati ọmọbinrin rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ mú fun ọmọkunrin rẹ. Nitoripe nwọn o yi ọmọkunrin rẹ pada lati ma tọ̀ mi lẹhin, ki nwọn ki o le ma sìn ọlọrun miran: ibinu OLUWA o si rú si nyin, on a si run ọ lojiji.