Nigbati ọmọ rẹ ba bi ọ lère lẹhin-ọla, wipe, Kini èredi ẹrí, ati ìlana, ati idajọ wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun filelẹ li aṣẹ fun nyin? Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun ọmọ rẹ pe, Ẹrú Farao li awa ti ṣe ni Egipti; OLUWA si fi ọwọ́ agbara mú wa jade lati Egipti wá. OLUWA si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ti o tobi ti o si buru hàn lara Egipti, lara Farao, ati lara gbogbo ara ile rẹ̀ li oju wa: O si mú wa jade lati ibẹ̀ wá, ki o le mú wa wọ̀ inu rẹ̀, lati fun wa ni ilẹ na ti o bura fun awọn baba wa. OLUWA si pa a laṣẹ fun wa, lati ma ṣe gbogbo ìlana wọnyi, lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun wa, fun ire wa nigbagbogbo, ki o le pa wa mọ́ lãye, bi o ti ri li oni yi. Yio si jẹ́ ododo wa, bi awa ba nṣọ́ ati ma ṣe gbogbo ofin wọnyi niwaju OLUWA Ọlọrun wa, bi o ti paṣẹ fun wa.
Kà Deu 6
Feti si Deu 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 6:20-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò