Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli. Mose si paṣẹ fun wọn, wipe, Li opin ọdún meje meje li akokò ọdún idasilẹ, ni ajọ agọ́. Nigbati gbogbo Israeli ba wá farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti on o gbé yàn, ki iwọ ki o kà ofin yi niwaju gbogbo Israeli li etí wọn. Kó awọn enia na jọ, awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọde, ati alejò rẹ ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki nwọn ki o le gbọ́, ati ki nwọn ki o le kọ ati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ati ki nwọn ki o ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi; Ati ki awọn ọmọ wọn, ti kò mọ̀, ki o le gbọ́, ki nwọn si kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngóke Jordani lọ lati gbà a.
Kà Deu 31
Feti si Deu 31
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 31:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò