OLUWA Ọlọrun, iwọ ti bẹ̀rẹsi fi titobi rẹ hàn fun iranṣẹ rẹ, ati ọwọ́ agbara rẹ: nitoripe Ọlọrun wo ni li ọrun ati li aiye, ti o le ṣe gẹgẹ bi iṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi iṣẹ-agbara rẹ? Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja si ìha keji, ki emi si ri ilẹ rere na ti mbẹ loke Jordani, òke daradara nì, ati Lebanoni. Ṣugbọn OLUWA binu si mi nitori nyin, kò si gbọ́ ti emi: OLUWA si wi fun mi pe, O to gẹ; má tun bá mi sọ ọ̀rọ yi mọ́. Gùn ori òke Pisga lọ, ki o si gbé oju rẹ soke si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù, ati si ìha ìla-õrùn, ki o si fi oju rẹ wò o: nitoripe iwọ ki yio gòke Jordani yi.
Kà Deu 3
Feti si Deu 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 3:24-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò