Deu 28:13-15

Deu 28:13-15 YBCV

OLUWA yio si fi ọ ṣe ori, ki yio si ṣe ìru; iwọ o si ma leke ṣá, iwọ ki yio si jẹ́ ẹni ẹhin; bi o ba fetisi aṣẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti mo pa fun ọ li oni, lati ma kiyesi on ati ma ṣe wọn; Iwọ kò si gbọdọ yà kuro ninu gbogbo ọ̀rọ ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, si ọtún, tabi si òsi, lati tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn. Yio si ṣe, bi iwọ kò ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ ti mo filelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo egún wọnyi yio ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ.