Deu 28:12-14

Deu 28:12-14 YBCV

OLUWA yio ṣí iṣura rere rẹ̀ silẹ fun ọ, ọrun lati rọ̀jo si ilẹ rẹ li akokò rẹ̀, ati lati busi iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: iwọ o si ma wín orilẹ-ède pupọ̀, iwọ ki yio si tọrọ. OLUWA yio si fi ọ ṣe ori, ki yio si ṣe ìru; iwọ o si ma leke ṣá, iwọ ki yio si jẹ́ ẹni ẹhin; bi o ba fetisi aṣẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti mo pa fun ọ li oni, lati ma kiyesi on ati ma ṣe wọn; Iwọ kò si gbọdọ yà kuro ninu gbogbo ọ̀rọ ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, si ọtún, tabi si òsi, lati tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn.