Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin. Ki ẹnyin ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ nyin, ki ẹnyin ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide. Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun-ọ̀na-ode rẹ: Ki ọjọ́ nyin ki o le ma pọ̀si i, ati ọjọ́ awọn ọmọ nyin, ni ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin lati fi fun wọn, bi ọjọ́ ọrun lori ilẹ aiye.
Kà Deu 11
Feti si Deu 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 11:18-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò