Deu 11:1-4

Deu 11:1-4 YBCV

NITORINA ki iwọ ki o fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma pa ikilọ̀ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ofin rẹ̀ mọ́, nigbagbogbo. Ki ẹnyin ki o si mọ̀ li oni: nitoripe awọn ọmọ nyin ti emi nsọ fun ti kò mọ̀, ti kò si ri ibawi OLUWA Ọlọrun nyin, titobi rẹ̀, ọwọ́ agbara rẹ̀, ati ninà apa rẹ̀, Ati iṣẹ-àmi rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, ti o ṣe lãrin Egipti, si Farao ọba Egipti, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀; Ati ohun ti o ṣe si ogun Egipti, si ẹṣin wọn, ati kẹkẹ́-ogun wọn; bi o ti mu ki omi Okun Pupa bò wọn mọlẹ bi nwọn ti nlepa nyin lọ, ati bi OLUWA ti run wọn titi di oni-oloni