Dan 7:13-14

Dan 7:13-14 YBCV

Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀. A si fi agbara ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sìn i; agbara ijọba rẹ̀ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a kì yio rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyiti a kì yio le parun.