Ọba si dahùn, o wipe, Ko ṣepe eyi ni Babeli nla, ti emi ti fi lile agbara mi kọ́ ni ile ijọba, ati fun ogo ọlanla mi? Bi ọ̀rọ na si ti wà lẹnu ọba, ohùn kan fọ̀ lati ọrun wá, pe, Nebukadnessari, ọba, iwọ li a sọ fun; pe, a gba ijọba kuro lọwọ rẹ. A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.
Kà Dan 4
Feti si Dan 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Dan 4:30-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò