Dan 2:34-35

Dan 2:34-35 YBCV

Iwọ ri titi okuta kan fi wá laisi ọwọ, o si kọlu ere na lẹsẹ rẹ̀, ti iṣe ti irin ati amọ̀, o si fọ́ wọn tũtu. Nigbana li a si fọ irin, amọ̀, idẹ, fadaka ati wura pọ̀ tũtu, o si dabi iyangbo ipaka nigba ẹ̀run; afẹfẹ si gbá wọn lọ, ti a kò si ri ibi kan fun wọn mọ́: okuta ti o si fọ ere na si di òke nla, o si kún gbogbo aiye.