Nigbana ni Danieli lọ si ile rẹ̀, o si fi nkan na hàn fun Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli. Nigbana ni a fi aṣiri na hàn fun Danieli ni iran li oru, Danieli si fi ibukún fun Ọlọrun, Oluwa ọrun. Danieli dahùn o si wipe, Olubukún ni orukọ Ọlọrun titi lai; nitori tirẹ̀ li ọgbọ́n ati agbara. O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye: O fi ohun ijinlẹ ati aṣiri hàn: o mọ̀ ohun ti o wà li òkunkun, lọdọ rẹ̀ ni imọlẹ si wà. Mo dupẹ lọwọ rẹ, mo si fi iyìn fun ọ, iwọ Ọlọrun awọn baba mi, ẹniti o fi ọgbọ́n ati agbara fun mi, ti o si fi ohun ti awa bère lọwọ rẹ hàn fun mi nisisiyi: nitoriti iwọ fi ọ̀ran ọba hàn fun wa nisisiyi.
Kà Dan 2
Feti si Dan 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Dan 2:17-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò