Dan 12:6-7

Dan 12:6-7 YBCV

Ẹnikan si wi fun ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla ti o duro lori omi odò pe, opin ohun iyanu wọnyi yio ti pẹ to? Emi si gbọ́, ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla, ti o duro loju omi odò na, o gbé ọwọ ọtún ati ọwọ òsi rẹ̀ si ọrun, o si fi Ẹniti o wà titi lai nì bura pe, yio jẹ akokò kan, awọn akokò, ati ãbọ akokò; nigbati yio si ti ṣe aṣepe ifunka awọn enia mimọ́, gbogbo nkan wọnyi li a o si pari.