Kol 3:9-17

Kol 3:9-17 YBCV

Ẹ má si ṣe purọ́ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣe rẹ̀; Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a: Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo. Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra; Ẹ mã farada a fun ara nyin, ẹ si mã dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sun si ẹnikan: bi Kristi ti darijì nyin, gẹgẹ bẹ̃ni ki ẹnyin ki o mã ṣe pẹlu. Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, ti iṣe àmure ìwa pipé. Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mã ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa. Ohunkohun ti ẹnyin ba si nṣe li ọ̀rọ tabi ni iṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn li orukọ Jesu Oluwa, ẹ mã fi ọpẹ́ fun Ọlọrun Baba nipasẹ rẹ̀.