Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi: Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi adabọwọ irẹlẹ ati bibọ awọn angẹli lọ́ ere nyin gbà lọwọ nyin, ẹniti nduro lori nkan wọnni ti o ti ri, ti o nti ipa ero rẹ̀ niti ara ṣeféfe asan, Ti kò si di Ori nì mu ṣinṣin, lati ọdọ ẹniti a nti ipa orike ati iṣan pese fun gbogbo ara, ti a si nso o ṣọkan pọ, ti o si ndagba nipa ibisi Ọlọrun. Bi ẹnyin ba ti kú pẹlu Kristi kuro ninu ipilẹṣẹ aiye, ẽhatiṣe ti ẹnyin ntẹriba fun ofin bi ẹnipe ẹnyin wà ninu aiye, Maṣe fọwọkàn, maṣe tọ́wò, maṣe fọwọbà, (Gbogbo eyiti yio ti ipa lilo run), gẹgẹ bi ofin ati ẹkọ́ enia? Awọn nkan ti o ni afarawe ọgbọ́n nitõtọ, ni adabọwọ ìsin, ati irẹlẹ, ati ìpọn-ara-loju, ṣugbọn ti kò ni ere kan ninu fun ifẹkufẹ ara.
Kà Kol 2
Feti si Kol 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Kol 2:16-23
4 Awọn ọjọ
Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò