Kol 2:16-19

Kol 2:16-19 YBCV

Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi: Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi adabọwọ irẹlẹ ati bibọ awọn angẹli lọ́ ere nyin gbà lọwọ nyin, ẹniti nduro lori nkan wọnni ti o ti ri, ti o nti ipa ero rẹ̀ niti ara ṣeféfe asan, Ti kò si di Ori nì mu ṣinṣin, lati ọdọ ẹniti a nti ipa orike ati iṣan pese fun gbogbo ara, ti a si nso o ṣọkan pọ, ti o si ndagba nipa ibisi Ọlọrun.