PAULU, Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa, Si awọn enia mimọ́ ati awọn ará wa olõtọ ninu Kristi ti o wà ni Kolosse: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa. Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, awa si ngbadura fun nyin nigbagbogbo, Nigbati awa gburó igbagbọ́ nyin ninu Kristi Jesu, ati ifẹ ti ẹnyin ni si gbogbo awọn enia mimọ́, Nitori ireti ti a gbé kalẹ fun nyin li ọrun, nipa eyiti ẹnyin ti gbọ́ ṣaju ninu ọ̀rọ otitọ ti ihinrere, Eyiti o de ọdọ nyin, ani bi o ti nso eso pẹlu ni gbogbo aiye ti o si npọ si i, bi o ti nṣe ninu nyin pẹlu, lati ọjọ ti ẹnyin ti gbọ́, ti ẹnyin si ti mọ̀ ore-ọfẹ Ọlọrun li otitọ
Kà Kol 1
Feti si Kol 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Kol 1:1-6
15 Days
If you’re new to Jesus, new to the Bible, or helping a friend who is - Start Here. For the next 15 days, these 5-minute audio guides will walk you step-by-step through two fundamental Bible books: Mark and Colossians. Track Jesus’ story and discover the basics of following Him, with daily questions for individual reflection or group discussion. Follow once to get started, then invite a friend and follow again!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò