Egbe ni fun ẹnyin ti ẹ nfẹ́ ọjọ Oluwa! kili eyi o jasi fun nyin? ọjọ Oluwa òkunkun ni, kì isi iṣe imọlẹ. Gẹgẹ bi enia ti o sa fun kiniun, ti beari si pade rẹ̀; tabi ti o wọ̀ inu ile, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ tì lara ogiri, ti ejò si bù u jẹ. Ọjọ Oluwa kì o ha ṣe òkunkun laiṣe imọlẹ? ani òkunkun biribiri, laisi imọlẹ ninu rẹ̀? Mo korira, mo si kẹgàn ọjọ asè nyin, emi kì o si gbõrùn ọjọ ajọ ọ̀wọ nyin. Bi ẹnyin tilẹ rú ẹbọ sisun ati ẹbọ jijẹ nyin si mi, emi kì o si gbà wọn: bẹ̃ni emi ki yio nani ẹbọ ọpẹ́ ẹran abọ́pa nyin. Mu ariwo orin rẹ kuro lọdọ mi; nitori emi kì o gbọ́ iró adùn fioli rẹ. Ṣugbọn jẹ ki idajọ ki o ṣàn silẹ bi omi, ati ododo bi iṣàn omi nla. Ẹnyin ha ti rubọ si mi, ẹ ha ti ta mi lọrẹ li aginjù li ogoji ọdun, ẹnyin ile Israeli. Ṣugbọn ẹnyin ti rù agọ Moloku ati Kiuni nyin, awọn ere nyin, irawọ̀ òriṣa nyin, ti ẹ ṣe fun ara nyin. Nitorina, emi o mu ki ẹ lọ si igbèkun rekọja Damasku, li Oluwa wi, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
Kà Amo 5
Feti si Amo 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Amo 5:18-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò