Iṣe Apo 9:9-11

Iṣe Apo 9:9-11 YBCV

O si gbé ijọ mẹta li airiran, kò si jẹ, bẹ̃ni kò si mu. Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò o, emi niyi, Oluwa. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu, ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura.