Iṣe Apo 9:23-25

Iṣe Apo 9:23-25 YBCV

Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a: Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mu u li oru, nwọn si sọ̀ ọ kalẹ lara odi ninu agbọ̀n.