Iṣe Apo 9:10-12

Iṣe Apo 9:10-12 YBCV

Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò o, emi niyi, Oluwa. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu, ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura. On si ti ri ọkunrin kan li ojuran ti a npè ni Anania o wọle, o si fi ọwọ́ le e, ki o le riran.