Filippi si yà ẹnu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ lati ibi iwe-mimọ́ yi, o si wasu Jesu fun u. Bi nwọn si ti nlọ li ọ̀na, nwọn de ibi omi kan: iwẹfa na si wipe, Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi? Filippi si wipe, Bi iwọ ba gbagbọ́ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ. O si dahùn o ni, Mo gbagbọ́ pe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun ni. O si paṣẹ ki kẹkẹ́ duro jẹ: awọn mejeji si sọkalẹ lọ sinu omi, ati Filippi ati iwẹfa; o si baptisi rẹ̀. Nigbati nwọn si jade kuro ninu omi, Ẹmí Oluwa ta Filippi pá, iwẹfa kò si ri i mọ́: nitoriti o mbá ọ̀na rẹ̀ lọ, o nyọ̀. Ni Asotu li a si ri Filippi; bi o si ti nkọja lọ, o nwasu ihinrere ni gbogbo ilu, titi o fi de Kesarea.
Kà Iṣe Apo 8
Feti si Iṣe Apo 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 8:35-40
3 Awọn ọjọ
Ìbí, ikú àti àjíǹde Jésù mú ìròyìn ayọ̀ náà wá. Ìròyìn ayọ̀ yìí ni ó ti yọrí sí ìgbàlà arayé. Nítorí náà, gbogbo ẹni tí a ti gbàlà ni Jésù Olúwa àti Olùgbàlà ti pa á láṣẹ fún láti dìde fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ ìkéde-ìhìnrere, èyí tíí ṣe pínpín ìròyìn ayọ̀ yìí kan náà fún àwọn ẹlòmíràn tí kò tíì di ẹni ìgbàlà.
5 Awọn ọjọ
Ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí yóò dì ọ́ ní àmùrè pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgboyà láti wàásù Jesu. Jẹ́ ìmọ̀lẹ̀ láàrin òkùnkùn!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò