Iṣe Apo 8:1-3

Iṣe Apo 8:1-3 YBCV

SAULU si li ohùn si ikú rẹ̀. Li akoko na, inunibini nla kan dide si ijọ ti o wà ni Jerusalemu; a si tú gbogbo wọn kalẹ já àgbegbe Judea on Samaria, afi awọn aposteli. Awọn enia olufọkànsin si dì okú Stefanu, nwọn si pohùnrére ẹkún kikan sori rẹ̀. Ṣugbọn Saulu, o ndà ijọ enia Ọlọrun ru, o nwọ̀ ojõjũle, o si nmu awọn ọkunrin ati obinrin, o si nfi wọn sinu tubu.