Iṣe Apo 7:8-16

Iṣe Apo 7:8-16 YBCV

O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila. Awọn baba nla si ṣe ilara Josefu, nwọn si tà a si Egipti: ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. O si yọ ọ kuro ninu ipọnju rẹ̀ gbogbo, o si fun u li ojurere ati ọgbọ́n li oju Farao ọba Egipti; on si fi i jẹ bãlẹ Egipti ati gbogbo ile rẹ̀. Iyan kan si wá imu ni gbogbo ilẹ Egipti ati ni Kenaani, ati ipọnju pipọ: awọn baba wa kò si ri onjẹ. Ṣugbọn nigbati Jakọbu gbọ́ pe alikama mbẹ ni Egipti, o rán awọn baba wa lọ lẹrinkini. Ati nigba keji Josefu fi ara rẹ̀ hàn fun awọn arakunrin rẹ̀; a si fi awọn ará Josefu hàn fun Farao. Josefu si ranṣẹ, o si pè Jakọbu baba rẹ̀, ati gbogbo awọn ibatan rẹ̀ sọdọ rẹ̀, arundilọgọrin ọkàn. Jakọbu si sọkalẹ lọ si Egipti, o si kú, on ati awọn baba wa, A si gbe wọn lọ si Sikemu, a si tẹ́ wọn sinu ibojì ti Abrahamu rà ni iye-owo fadaka lọwọ awọn ọmọ Emoru baba Sikemu.