Iṣe Apo 7:20-25

Iṣe Apo 7:20-25 YBCV

Li akokò na li a bí Mose, ẹniti o li ẹwà pipọ, ti nwọn si bọ́ li oṣù mẹta ni ile baba rẹ̀: Nigbati nwọn si gbe e sọnù, ọmọbinrin Farao he e, o si tọ́ ọ dàgba li ọmọ ara rẹ̀. A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe. Nigbati o si di ẹni iwọn ogoji ọdún, o sọ si i lọkan lati lọ ibẹ̀ awọn ọmọ Israeli ará rẹ̀ wò. Nigbati o si ri ọkan ninu wọn ti a njẹ ni ìya, o gbejà rẹ̀, o gbẹsan ẹniti nwọn njẹ ni ìya, o si lu ara Egipti na pa: O si ṣebi awọn ará on mọ̀ bi Ọlọrun yio ti ti ọwọ́ on gbà wọn: ṣugbọn nwọn kò mọ̀.