NIGBANA li olori alufa wipe, Nkan wọnyi ha ri bẹ̃ bi?
On si wipe, Alàgba, ará, ati baba, ẹ fetisilẹ̀; Ọlọrun ogo fi ara hàn fun Abrahamu baba wa, nigbati o wà ni Mesopotamia, ki o to ṣe atipo ni Harani,
O si wi fun u pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati lọdọ awọn ibatan rẹ, ki o si wá si ilẹ ti emi ó fi hàn ọ.
Nigbana li o jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, o si ṣe atipo ni Harani: lẹhin igbati baba rẹ̀ kú, Ọlọrun mu u ṣipo pada wá si ilẹ yi, nibiti ẹnyin ngbé nisisiyi.
Kò si fun u ni ini kan, ani to bi ẹsẹ ilẹ kan; ṣugbọn o leri pe, on ó fi i fun u ni ilẹ-nini, ati fun awọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati kò ti ili ọmọ.
Ọlọrun si sọ bayi pe, irú-ọmọ rẹ̀ yio ṣe atipo ni ilẹ àjeji; nwọn ó si sọ wọn di ẹru, nwọn o si pọ́n wọn loju ni irinwo ọdún.
Ọlọrun wipe, Orilẹ-ède na ti nwọn o ṣe ẹrú fun, li emi ó da lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade kuro, nwọn o si wá sìn mi nihinyi.
O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila.
Awọn baba nla si ṣe ilara Josefu, nwọn si tà a si Egipti: ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.
O si yọ ọ kuro ninu ipọnju rẹ̀ gbogbo, o si fun u li ojurere ati ọgbọ́n li oju Farao ọba Egipti; on si fi i jẹ bãlẹ Egipti ati gbogbo ile rẹ̀.
Iyan kan si wá imu ni gbogbo ilẹ Egipti ati ni Kenaani, ati ipọnju pipọ: awọn baba wa kò si ri onjẹ.
Ṣugbọn nigbati Jakọbu gbọ́ pe alikama mbẹ ni Egipti, o rán awọn baba wa lọ lẹrinkini.
Ati nigba keji Josefu fi ara rẹ̀ hàn fun awọn arakunrin rẹ̀; a si fi awọn ará Josefu hàn fun Farao.
Josefu si ranṣẹ, o si pè Jakọbu baba rẹ̀, ati gbogbo awọn ibatan rẹ̀ sọdọ rẹ̀, arundilọgọrin ọkàn.
Jakọbu si sọkalẹ lọ si Egipti, o si kú, on ati awọn baba wa,
A si gbe wọn lọ si Sikemu, a si tẹ́ wọn sinu ibojì ti Abrahamu rà ni iye-owo fadaka lọwọ awọn ọmọ Emoru baba Sikemu.
Ṣugbọn bi akokò ileri ti Oluwa ṣe fun Abrahamu ti kù si dẹ̀dẹ, awọn enia na nrú, nwọn si nrẹ̀ ni Egipti,
Titi ọba miran fi jẹ lori Egipti ti kò mọ̀ Josefu.
On na li o ṣe àrekerekè si awọn ibatan wa, nwọn si hùwa buburu si awọn baba wa, tobẹ̃ ti nwọn fi já awọn ọmọ-ọwọ wọn kuro lọwọ wọn nitori ki nwọn ki o máṣe yè.
Li akokò na li a bí Mose, ẹniti o li ẹwà pipọ, ti nwọn si bọ́ li oṣù mẹta ni ile baba rẹ̀:
Nigbati nwọn si gbe e sọnù, ọmọbinrin Farao he e, o si tọ́ ọ dàgba li ọmọ ara rẹ̀.
A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe.
Nigbati o si di ẹni iwọn ogoji ọdún, o sọ si i lọkan lati lọ ibẹ̀ awọn ọmọ Israeli ará rẹ̀ wò.
Nigbati o si ri ọkan ninu wọn ti a njẹ ni ìya, o gbejà rẹ̀, o gbẹsan ẹniti nwọn njẹ ni ìya, o si lu ara Egipti na pa:
O si ṣebi awọn ará on mọ̀ bi Ọlọrun yio ti ti ọwọ́ on gbà wọn: ṣugbọn nwọn kò mọ̀.
O si di ijọ keji o yọ si wọn bi nwọn ti njà, on iba si pari rẹ̀ fun wọn, o wipe, Alàgba, ará li ẹnyin; ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ohun ti kò tọ́ si ara nyin?
Ṣugbọn ẹniti o finran si ẹnikeji rẹ̀ tì i kuro, o wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ wa?
Iwọ nfẹ pa mi gẹgẹ bi o ti pa ará Egipti laná?
Mose si sá nitori ọ̀rọ yi, o si wa ṣe atipo ni ilẹ Midiani, nibiti o gbé bí ọmọ meji.
Nigbati ogoji ọdún si pé, angẹli Oluwa farahàn a ni ijù, li òke Sinai, ninu ọwọ́ iná ni igbẹ́.
Nigbati Mose si ri i, ẹnu yà a si iran na: nigbati o si sunmọ ọ lati wò o fín, ohùn Oluwa kọ si i,
Wipe, Emi li Ọlọrun awọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Mose si warìri, kò si daṣa lati wò o mọ́.
Oluwa si wi fun u pe, Tú bata rẹ kuro li ẹsẹ rẹ: nitori ibi ti iwọ gbé duro nì ilẹ mimọ́ ni.
Ni riri mo ti ri ipọnju awọn enia mi ti mbẹ ni Egipti, mo si ti gbọ́ gbigbin wọn, mo si sọkalẹ wá lati gbà wọn. Wá nisisiyi, emi o si rán ọ lọ si Egipti.