Iṣe Apo 5:7-11

Iṣe Apo 5:7-11 YBCV

O si to bi ìwọn wakati mẹta, aya rẹ̀ laimọ̀ ohun ti o ti ṣe, o wọle. Peteru si da a lohùn pe, Wi fun mi, bi iye bayi li ẹnyin tà ilẹ na? O si wipe, Lõtọ iye bẹ̃ ni. Peteru si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fohùn ṣọkan lati dán Ẹmí Oluwa wò? wò o, ẹsẹ awọn ti o sinkú ọkọ rẹ mbẹ li ẹnu ọ̀na, nwọn o si gbé ọ jade. O si ṣubu lulẹ li ẹsẹ rẹ̀ lojukanna, o si kú: awọn ọdọmọkunrin si wọle, nwọn bá a o kú, nwọn si gbé e jade, nwọn sin i lẹba ọkọ rẹ̀. Ẹru nla si ba gbogbo ijọ, ati gbogbo awọn ti o gbọ́ nkan wọnyi.