Iṣe Apo 5:33-39

Iṣe Apo 5:33-39 YBCV

Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn. Ṣugbọn ọkan ninu ajọ igbimọ, ti a npè ni Gamalieli, Farisi ati amofin, ti o ni iyìn gidigidi lọdọ gbogbo enia, o dide duro, o ni ki a mu awọn aposteli bì sẹhin diẹ; O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ọkunrin Israeli, ẹ kiyesi ara nyin li ohun ti ẹnyin npete ati ṣe si awọn ọkunrin wọnyi. Nitori ṣaju ọjọ wọnyi ni Teuda dide, o nwipe ẹni nla kan li on; ẹniti ìwọn irinwo ọkunrin gbatì: ẹniti a pa; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a tú wọn ká, a si sọ wọn di asan. Lẹhin ọkunrin yi ni Juda ti Galili dide lakoko kikà enia, o si fà enia pipọ lẹhin rẹ̀: on pẹlu ṣegbé; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a fọn wọn ká. Njẹ emi wi fun nyin nisisiyi, Ẹ gafara fun awọn ọkunrin wọnyi, ki ẹ si jọwọ wọn jẹ: nitori bi ìmọ tabi iṣẹ yi ba jẹ ti enia, a o bì i ṣubu: Ṣugbọn bi ti Ọlọrun ba ni, ẹnyin kì yio le bì i ṣubu; ki o ma ba jẹ pe, a ri nyin ẹ mba Ọlọrun jà.