ṢUGBỌN ọkunrin kan ti a npè ni Anania, pẹlu Safira aya rẹ̀, tà ilẹ iní kan. O si yàn apakan pamọ́ ninu owo na, aya rẹ̀ ba a mọ̀ ọ pọ̀, o si mu apakan rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli. Ṣugbọn Peteru wipe, Anania, Ẽṣe ti Satani fi kún ọ li ọkàn lati ṣeke si Ẹmí Mimọ́, ti iwọ si fi yàn apakan pamọ́ ninu owo ilẹ na? Nigbati o wà nibẹ, tirẹ ki iṣe? nigbati a si ta a tan, kò ha wà ni ikawọ ara rẹ? Ẽha ti ṣe ti iwọ fi rò kini yi li ọkàn rẹ? enia ki iwọ ṣeke si bikoṣe si Ọlọrun. Nigbati Anania si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o ṣubu lulẹ, o si kú: ẹ̀ru nla si ba gbogbo awọn ti o gbọ́. Awọn ọdọmọkunrin si dide, nwọn dì i, nwọn si gbé e jade, nwọn si sin i.
Kà Iṣe Apo 5
Feti si Iṣe Apo 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 5:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò