Iṣe Apo 4:32-34

Iṣe Apo 4:32-34 YBCV

Ijọ awọn ti o gbagbọ́ si wà li ọkàn kan ati inu kan: kò si si ẹnikan ti o pè ohun kan ninu ohun ini rẹ̀ ni ti ara rẹ̀: ṣugbọn gbogbo nwọn ni gbogbo nkan ṣọkan. Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn. Nitori kò si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile tà wọn, nwọn si mu owo ohun ti nwọn tà wá.