Iṣe Apo 4:29-30

Iṣe Apo 4:29-30 YBCV

Njẹ nisisiyi, Oluwa, kiyesi ikilọ wọn: ki o si fifun awọn ọmọ-ọdọ rẹ lati mã fi igboiya gbogbo sọ ọ̀rọ rẹ. Ki iwọ si fi ninà ọwọ́ rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ.